Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 21:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí,ìwárìrì sì mú mi lára.

7. Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà níayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?

8. Irú ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojúwọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ-ọmọ wọn ní ojú wọn.

9. Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pá iná Ọlọ́run kò sí lára wọn.

10. Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì ísìíṣe; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun;

11. Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọnwẹ́ẹ́wẹ́ẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jó kiri.

Ka pipe ipin Jóòbù 21