Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 12:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá,Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.

23. Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.

24. Òun a gba àyà olú àwọn ènìyàn aráyé,A sì máa mú wọn wọ́ kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.

25. Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀,Òun a sì máa mú wọn tàsé ìrìn bí ọ̀mùtí.

Ka pipe ipin Jóòbù 12