Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 11:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ,ó sì ní ibú ju òkun lọ.

10. “Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sénà,tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdajọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?

11. Òun sáà mọ ènìyàn asán;àti pé ṣé bí òun bá rí ohunbúburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?

12. Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn yóò di ọlọgbọ́n,nígbà tí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ènìyàn.

13. “Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un,tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,

14. Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù,tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ.

15. Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láì ní àbàwọ́n,àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,

16. Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ,ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti ṣàn kọjá lọ.

17. Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísisinyìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.

18. Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.

19. Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,àní ènìyàn yóò máa wá ojú rere rẹ.

20. Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”

Ka pipe ipin Jóòbù 11