Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 1:10-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùṣí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ si ní ilẹ̀.

11. Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ”

12. Olúwa sì dá Sàtanì lóhùn wí pé, “Kíyèsí i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.”Bẹ́ẹ̀ ni Sàtanì jáde lọ kúrò níwájú Olúwa.

13. Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin:

14. Onísẹ́ kan sì tọ Jóòbù wá wí pé: “Àwọn ọ̀dà-màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn;

15. Àwọn ará Sábà sì kọ lù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà ṣá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”

16. Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lu tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi níkàn ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”

17. Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kádéà píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọ lù àwọn ìbákasíẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lupẹ̀lu wọ́n sì fi idà ṣá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”

18. Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnikàn dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n.

19. Sì kíyèsí i, ẹfúfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọ lu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọdọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.

20. Nígbà náà ni Jóòbù dìde, ó sì fa aṣọ ìgunwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà

21. wí pé:“Ní ìhòòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,ni ìhòòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ síbẹ̀. Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ,ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”

22. Nínú gbogbo èyí Jóòbù kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.

Ka pipe ipin Jóòbù 1