orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jónà 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Jónà Bínú Sí Àánú Tí Olúwa Fi Hàn

1. Ṣùgbọ́n ó ba Jónà nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀.

2. Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyi nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítórí èyí ni mo ṣé sá lọ sí Tásísí ní ìṣáájú: nitori èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà.

3. Ǹjẹ́ báyìí, Olúwa, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ.”

4. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”

5. Jónà sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni ibòòji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.

6. Olúwa Ọlọ́run sì pesè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jónà; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jónà sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà.

7. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ.

8. Ó sì ṣe, nígbà tí òòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jónà lórí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ.”

9. Ọlọ́run sì wí fún Jónà pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?”Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, Ó tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”

10. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.

11. Ṣùgbọ́n Nínéfè ní jù ọ̀kẹ́-mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ilú ńlá náà?”