Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 3:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àti àwọn ọmọ Júdà, àti àwọn ọmọ Jérúsálẹ́mù ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ara Gíríkì, kí ẹ̀yin báà le sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìnì wọn.

7. “Kíyèsì í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín.

8. Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Júdà, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Ṣábíà, fún orílẹ̀ èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.

9. Ẹ kéde èyí ní àárin àwọn aláìkọlà;Ẹ dira ogun,ẹ jí àwọn alágbára,Jẹ kí awọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun,

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 3