Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 3:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.

16. Olúwa yóò sí ké ramúramú láti Ṣíónì wá,yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jérúsálẹ́mù wá;àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtìṢùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,àti agbára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

17. “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,tí ń gbé Ṣíónì òkè mímọ́ mi.Ìgbà náà ni Jérúsálẹ́mù yóò jẹ́ mímọ́;àwọn àlejò kì yóò sì kó o mọ́.

18. “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè-ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa ṣàn fún wàrà;gbogbo odò Júdà tí ó gbẹ́ yóò máa ṣàn fún omi.Oríṣun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ile Olúwa wá,yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣítímù.

19. Ṣùgbọ́n Éjíbítì yóò di ahoro,Édómù yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Júdà,ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.

20. Ṣùgbọ́n Júdà yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,àti Jérúsálẹ́mù láti ìran dé ìran.

21. Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tíì wẹ̀nù.Nítorí Olúwa ń gbé Síónì.”

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 3