Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 3:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ẹ fi irin itulẹ yín rọ idà,àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀.Jẹ́ kí aláìlera wí pé,“Ara mi le koko.”

11. Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà láti gbogbo àyíká,kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri:Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ ṣọkalẹ̀, Olúwa.

12. “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojìJéhóṣáfátì ẹ̀yin aláìkọlà:nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jòkòó láti ṣeìdájọ́ àwọn aláìkọlà yí kákìri.

13. Ẹ tẹ̀ dòjé bọ̀ ọ́,nítorí ìkórè pọ́n:ẹ wá, ẹ ṣọ̀kalẹ̀;nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọnọpọ́n kún-à-kún-wọ́sílẹ̀nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”

14. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ní àfonífojì ìdájọ́,nítorí ọjọ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ní àfonífojì ìdájọ́.

15. Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.

16. Olúwa yóò sí ké ramúramú láti Ṣíónì wá,yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jérúsálẹ́mù wá;àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtìṢùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,àti agbára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

17. “Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,tí ń gbé Ṣíónì òkè mímọ́ mi.Ìgbà náà ni Jérúsálẹ́mù yóò jẹ́ mímọ́;àwọn àlejò kì yóò sì kó o mọ́.

18. “Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè-ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,àwọn òkè kéékèèkéé yóò máa ṣàn fún wàrà;gbogbo odò Júdà tí ó gbẹ́ yóò máa ṣàn fún omi.Oríṣun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ile Olúwa wá,yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣítímù.

19. Ṣùgbọ́n Éjíbítì yóò di ahoro,Édómù yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Júdà,ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.

20. Ṣùgbọ́n Júdà yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,àti Jérúsálẹ́mù láti ìran dé ìran.

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 3