Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 3:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, àti ní àkókò náà,nígbà tí èmi tún mú ìgbékùn Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà bọ̀.

2. Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀ èdè jọpẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jéhóṣáfátì.Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi,àti nítorí Ísírẹ́lì ìní mi,tí wọ́n fọ́nká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè,wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.

3. Wọ́n si ti di ibò fún àwọn ènìyàn mi;wọ́n sì ti fi ọmọdé-kùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan,wọ́n sì ta ọmọdé bìnrin kan fúnọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.

4. “Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tirè àti Ṣídónì, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Fílístínì? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹyín ṣe padà sórí ara yín.

5. Nítorí tí ẹ̀yín tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere daradara mi lọ sínú tẹ́ḿpìlì yín.

6. Àti àwọn ọmọ Júdà, àti àwọn ọmọ Jérúsálẹ́mù ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ara Gíríkì, kí ẹ̀yin báà le sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìnì wọn.

7. “Kíyèsì í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín.

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 3