Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 7:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ se pánṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Báálì, kí ẹ sì tọ Ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ.

10. Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” sé yíyè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìnira wọ̀nyí bí?

11. Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́sà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí.

12. “ ‘Ẹ lọ nísinsìn yìí sí ṣílò níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Ísírẹ́lì tí í ṣe ènìyàn mi.

13. Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn

14. Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí ṣílò sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé Tẹ́ḿpìlì nínú èyí tí ẹ ní ìgbàgbọ́, àyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín.

15. Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Éfúráímù.’

16. “Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ.

Ka pipe ipin Jeremáyà 7