Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ifẹ́ wúrà ni Bábílónì ní ọwọ́ Olúwa;ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí.Gbogbo orílẹ̀ èdè mu ọtí rẹ̀,wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.

8. Bábílónì yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́;sunkún fún un! Wá báàmù fún ìrora rẹ,bóyá yóò le wo ọ́ sàn.

9. “ ‘À bá ti wo Bábílónì sàn,ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀,kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè,ó ga àní títí dé òfurufù.’

10. “ ‘Olúwa ti dá wa láre,wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Síónì ohun tí OlúwaỌlọ́run wa ti ṣe.’

11. “Lọ ọfà wa kó mú, mú apata! Olúwa ti ru Ọba Médíà sókè,nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Bábílónì run. Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún Tẹ́ḿpìlì rẹ̀.

12. Gbé àsìá sókè sí odi Bábílónì!Ẹ ṣe àwọn ọmọ ogun gírí,ẹ pín àwọn olùsọ́ káàkiri,ẹ ṣètò àwọn tí yóò sápamọ́ Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde,òfin rẹ̀ sí àwọn ará Bábílónì.

13. Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀,tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé,àní àsìkò láti ké ọ kúrò!

14. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀,Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú,wọn yóò yọ ayọ̀, iṣẹ́gun lórí rẹ.

15. “Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀,o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51