Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. “Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀,o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.

16. Nígbà tí ará omi ọ̀run hóó mú kí òfùrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé.Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.

17. “Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọtí kò sì ní ìmọ̀, olúkùlúkùalágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀.Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn wọn kò ní èémí nínú.

18. Wọn kò já mọ́ nkànkan,wọ́n jẹ́ ohun ẹlẹ́yà nígbà tí ìdájọ́ wọnbá dé, wọn ó ṣègbé.

19. Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jákọ́bù kó rí bí ìwọ̀nyí;nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo,àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún, Olúwa alágbára ni orúkọ rẹ̀.

20. “Ìwọ ni kùmọ̀ ohun èlò ogun mi,ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀ èdè túútúú,èmi ó bà àwọn ilé Ọba jẹ́.

21. Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lúèmi ó pa awakọ̀

22. Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,pẹ̀lú rẹ, mo paàgbàlagbà àti ọmọdé,Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.

23. Pẹ̀lú rẹ, mo pa olùsọ́ àgùntànàti agbo àgùntàn rẹ̀;pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbẹ̀ àti màlúù,Pẹ̀lú rẹ, mo pa gómìnà àti àwọn alákòóṣo ìjọba rẹ̀.

24. “Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Bábílónì àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Síónì,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51