Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 50:38-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

39. “Nítorí náà àwọn ẹranko ijùpẹ̀lu ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀,abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀,a kì ó sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé,bẹ́ẹ̀ ni a kì ó ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.

40. Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọbaSódómù àti Gòmóràpẹ̀lú àwọn ìlú agbégbé wọn,”ni Olúwa wí,“kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀.

41. “Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ ogun láti ìhà àríwá;orílẹ̀ èdè ńlá àti àwọn Ọba pípọ̀ ni à ńgbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.

42. Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun,wọ́n burú wọn kò sì ní àánú.Wọ́n bú bí i rírú omi bí wọ́n ti se ń gun ẹsin wọn lọ.Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.

43. Ọba Bábílónì ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,ọwọ́ wọn sì rọ,ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.

44. Bí i kìnnìún tí ń bú láti igbó Jọ́dánì.N ó lé Bábílónì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kánmọ́ kánmọ́.Ta ni ẹni àyànfẹ́ náà tí n ó yàn?Ta ló dàbí mi, ta ló dàbí mi,ta ló sì le dojú ìjà kọmí?”

45. Nítorí náà, gbọ́ ohun tí Olúwa sọ nípa Bábílónìẹni tí ó gbìmọ̀ lòdìsí Bábílónì; n ó sì paagbo ẹran wọn run.

46. Ní dídún fèrè Bábílónìgbogbo ilẹ̀ ayé yóò mì tìtìigbe rẹ̀ yóò sì búja gbogboàwọn orílẹ̀ èdè.

Ka pipe ipin Jeremáyà 50