Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 50:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Mo dẹ pàkúté sílẹ̀fún ọ ìwọ Bábílónì,kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.

25. Olúwa ti kó àwọn ohun èlòìjà rẹ̀ jáde, nítorí pé OlúwaỌlọ́run ọmọ ogun ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Bábílónì.

26. Ẹ dìde sí láti ilẹ̀ jínjínpárun pátapáta láìṣẹ́kù.

27. Pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́àgùntàn rẹ̀, jẹ́ kí a kówọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n!Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé,àkókò ìbẹ̀wò wọn.

28. Tẹ́tí sí àwọn tí ó sálọ tí ó sì sálà láti Bábílónì,sì sọ ní Síónì, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san,ẹ̀san fún tẹ́ḿpílì rẹ̀.

29. “Pe ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Bábílónì,ẹ doti iyikakiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà.Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbógbó èyí ti o ti ṣé,ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ síi, nítorí tí ó ti gberagasí Olúwa, sí Ẹni-MÍMỌ̀ Ísirẹ́lì.

30. Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọnológun lẹ́nu mọ́,”ní Olúwa wí.

31. “Wò ó, èmi lòdì sí àwọn onígbéraga,”ni Olúwa Ọlọ́run,“ọmọ ogun wí, nítorí ọjọ́ rẹti dé tí ìwọ yóò jìyà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 50