Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 5:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Èmi kì yóò ṣàì fìyà jẹ wọ́n fún èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra milára irú orílẹ̀ èdè bí èyí bí?

10. “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,ẹ má ṣe pa wọ́n run pátapáta.Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.

11. Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdàti jẹ́ aláìsòdodo sí mi,”ni Olúwa wí.

12. Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa;wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan!Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá;àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.

13. Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”

14. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run alágbára wí:“Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí;Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná,àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.

15. Áà, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì,” ni Olúwa wí,“Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè láti ọ̀nà jínjìn dìde sí i yínOrílẹ̀ èdè ìgbàanì àti alágbára nìàwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀,tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.

16. Àpò ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a sígbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.

17. Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ,àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin,wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ,wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.Pẹ̀lú idà ni wọn ó runìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 5