Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 5:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwaàti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,wọ́n sì ti já ìdè.

6. Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,ìkokò ihà yóò sì pa wọ́n run,ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yínẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,apadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.

7. “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.Mo pèṣè fún gbogbo àìní wọn,síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágàwọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbérè.

8. Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,tí ó lágbára, wọ́n sì ń sunkún sí aya arákùnrin wọn.

9. Èmi kì yóò ṣàì fìyà jẹ wọ́n fún èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra milára irú orílẹ̀ èdè bí èyí bí?

10. “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,ẹ má ṣe pa wọ́n run pátapáta.Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.

11. Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdàti jẹ́ aláìsòdodo sí mi,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 5