Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 5:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Lọ sókè àti sódò àwọn òpó Jérúsálẹ́mùWò yíká, kí o sì mọ̀,kí o sì wá kiriBí o bá le è rí ẹnìkan,tí ó jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo,N ó dárí jìn ìlú yìí.

2. Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

3. Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n.Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà.Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ,wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.

4. Èmi sì rò pé, “talákà ni àwọn yìíwọn kò lóyenítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa,àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.

5. Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwaàti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,wọ́n sì ti já ìdè.

6. Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,ìkokò ihà yóò sì pa wọ́n run,ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yínẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,apadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.

7. “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.Mo pèṣè fún gbogbo àìní wọn,síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágàwọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbérè.

8. Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,tí ó lágbára, wọ́n sì ń sunkún sí aya arákùnrin wọn.

9. Èmi kì yóò ṣàì fìyà jẹ wọ́n fún èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra milára irú orílẹ̀ èdè bí èyí bí?

10. “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,ẹ má ṣe pa wọ́n run pátapáta.Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.

Ka pipe ipin Jeremáyà 5