Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 49:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nípa ti Ámónì:Ohun tí Olúwa sọ nìyìí:“Ísírẹ́lì kò ha ní ọmọkùnrin?Ṣé kò ha ní àrólé bí?Kí ló wá dé tí Mákómù fi jogún Gádì?Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?

2. Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,”ni Olúwa wí;“nígbà tí èmi yóò mú ìdágìrì ogun bá Rábàtí Ámónì yóò sì di òkítì ahoro,gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná.Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóòlé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,”ni Olúwa wí.

3. “Pohùnréré ẹkún ìwọ Hésíbónìnítorí Áì tí rún, kígbe jádeẹ̀yin ènìyàn Rábà, ẹ wọ aṣọọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sárésókè sódò nínú ọgbà nítoríMákómù yóò lọ sí ìgbèkùnpẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.

4. Kí ló dé tí ẹ fi ń fi àfonífojì yín yangàn?Ẹ fi àfonífojì yín yangàn pẹ̀lú èṣo rere,ẹ̀yin ọmọbìnrin aláìsòótọ́.Gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé,‘ta ni yóò kò mí lójú?’

5. Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹláti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,”ni Olúwa wí:

6. “Olúwa àwọn ọmọ ogun.Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì sí ẹnìkantí yóò dá ìkólọ Ámónì padà,”ni Olúwa wí.

7. Nípa Édómù:Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí:“Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temánì?Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè?Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

8. Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò,ìwọ tí ó ń gbé níDédánì nítorí èmi yóò múibi wá sórí Ísọ̀ ní àkókò tí èmi ó fìyà jẹ́ẹ́.

Ka pipe ipin Jeremáyà 49