Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 48:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,ìlú kan kò sì ní le là.Àfonífojì yóò di ahoroàti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

9. Fi iyọ̀ sí Móábù,nítorí yóò ṣègbé,àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoroláìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.

10. “Ìfibú ni fún ẹni tí ó dúró láti ṣe iṣẹ́ Olúwa,ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.

11. “Móábù ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wábí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejìkò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,òórùn rẹ̀ kò yí padà.

12. Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,”ni Olúwa wí,“nígbà tí n ó rán àwọn tí ó da ọtí láti inú àwọn ìgòtí wọ́n ó sì dà á síta;Wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo,wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.

13. Nígbà náà Móábù yóò sì tú u nítorí kémósì,bí ojú ti í ti ilé Ísírẹ́lìnígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Bétélì.

14. “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘ajagun ni wá,alágbára ní ogun jíjà’?

15. A ó pa Móábù run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

16. “Ìṣubú Móábù súnmọ́;ìpọ́njú yóò dé kánkán.

17. Ẹ dárò fún, gbógbó ẹ̀yin tí ó yí i kágbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹtítóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’

18. “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Díbónì,nítorí tí ẹni tí ó pa Móábù runyóò dojúkọ ọ́yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.

Ka pipe ipin Jeremáyà 48