Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 48:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Móábù yóò di wíwó palẹ̀;àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.

5. Wọ́n gòkè lọ sí Lúhítì,wọ́n ń sunkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;ní ojú ọ̀nà sí Horonáímùigbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.

6. Sá! Àsálà fún ẹ̀mí rẹ;kí o dàbí igbó ní aṣálẹ̀.

7. Níwọ̀n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,Sémọ́sì náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùnpẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.

8. Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,ìlú kan kò sì ní le là.Àfonífojì yóò di ahoroàti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

9. Fi iyọ̀ sí Móábù,nítorí yóò ṣègbé,àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoroláìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.

10. “Ìfibú ni fún ẹni tí ó dúró láti ṣe iṣẹ́ Olúwa,ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.

11. “Móábù ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wábí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejìkò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,òórùn rẹ̀ kò yí padà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 48