Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 44:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Júdà, tí wọ́n ṣetán láti lọ Éjíbítì. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn.

13. Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Éjíbítì pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jérúsálẹ́mù.

14. Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Júdà tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Éjíbítì tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Júdà, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mèlòó kan.”

15. Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Éjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremáyà.

16. “Wọn sì wí pé: Àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ni orúkọ Olúwa.

17. Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ni àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù. Nígbà naà àwa ní ounjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi

18. Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí ayaba ọrun sílẹ̀ àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.”

19. Obìnrin náà fi kun-un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rúbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”

20. Wàyí o, Jeremáyà sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé,

21. “Ṣe Ọlọ́run kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Júdà àti àwọn ìgboro Jérúsálẹ́mù láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá rẹ, àwọn Ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú.

22. Nígbà tí Ọlọ́run kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìbínú gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí.

23. Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́ràn síi lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe ríi.”

24. Nígbà náà ni Jeremáyà dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Júdà tí ó wà ní Éjíbítì.

25. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ lórí sísun tùràrí àti dída ọtí sí orí ère ayaba ọ̀run ṣẹ.’“Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.

Ka pipe ipin Jeremáyà 44