Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 43:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jeremáyà párí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan.

2. Ásáríyà ọmọ Hòsáyà àti Jóhánánì ọmọ Káréà, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremáyà pé, “Irọ́ ló ń pa! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí Éjíbítì láti tẹ̀dó síbẹ̀.’

3. Ṣùgbọ́n Bárúkù ọmọ Néríà ń kó sí ọ lọ́kàn sí wa láti fàwá lé Bábílónì lọ́wọ́, kí wọn le pa wá tàbí kó wa sí ìgbékùn Bábílónì.”

4. Nítorí náà, Jóhánánì ti Káréà àti àwọn ọ̀gágun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Júdà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 43