Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 39:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí wọ́n ṣe kó Jérúsálẹ́mù nìyìí: Ní ọdún kẹsàn-án Sedekáyà Ọba Júdà, nínú oṣù kẹwàá. Nebukadinésárì Ọba gbógun ti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì gẹ̀gùn tì í.

2. Ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹrin ọdún kọkànlá Nebukadinésárì wọ́n ya wọ odi ìlú.

3. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì wá, wọ́n sì jókòó ní àárin ẹnubodè Nágálì Sárésérì.

4. Nígbà tí Sedekáyà Ọba Júdà àti àwọn ọmọ ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà Ọba lọ láàrin ẹnubodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.

5. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì lé wọn, wọ́n bá Sedekáyà láàrin ihà Jẹ́ríkò. Wọ́n mú un ní ìgbékùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àti Rábílà ní ilẹ̀ Hámátì, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

6. Níbẹ̀ ní Rábílà, ni Ọba Bábílónì ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekáyà lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Júdà.

7. Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Bábílónì.

8. Àwọn Bábílónì dáná sun ààfin Ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin Jeremáyà 39