Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 37:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremáyà.

3. Ṣedekáyà Ọba sì rán Jéhúkálì ọmọ Semeláyà àti Sefanáyà ọmọ Máséyà sí Jeremáyà wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

4. Nígbà yìí Jeremáyà sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrin àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú.

5. Àwọn ọmọ ogun Fáráò ti jáde kúrò nílẹ̀ Éjíbítì àti nígbà tí àwọn ará Bábílónì tó ń ṣàtìpó ní Jérúsálẹ́mù gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jérúsálẹ́mù.

6. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run wá:

7. “Èyí ni, ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ fún Ọba àwọn Júdà tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Éjíbítì.

8. Nígbà náà ni àwọn ará Bábílónì yóò padà láti gbógun ti ìlú. Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀.’

Ka pipe ipin Jeremáyà 37