Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 37:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sedekáyà ọmọ Jòsáyà sì jọba nípò Kóráyà ọmọ Jéhóíákímù ẹni tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì fi jẹ Ọba ní ilẹ̀ Júdà.

2. Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremáyà.

3. Ṣedekáyà Ọba sì rán Jéhúkálì ọmọ Semeláyà àti Sefanáyà ọmọ Máséyà sí Jeremáyà wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

4. Nígbà yìí Jeremáyà sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrin àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú.

5. Àwọn ọmọ ogun Fáráò ti jáde kúrò nílẹ̀ Éjíbítì àti nígbà tí àwọn ará Bábílónì tó ń ṣàtìpó ní Jérúsálẹ́mù gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jérúsálẹ́mù.

6. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run wá:

Ka pipe ipin Jeremáyà 37