Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 36:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹrin Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé:

2. “Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Ísírẹ́lì àti ti Júdà, àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Jòsáyà títí di òní.

3. Ó lè jẹ́ wí pé ilé Júdà yóò gbọ́ gbogbo ibi tí mo ti pinnu láti ṣe fún wọn; kí wọn kí ó sì yípadà, olúkúlùkù wọn kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀. Kí èmi kí ó lè dárí àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n.”

4. Nígbà náà ni Jeremáyà pe Bárúkì ọmọ Neráyà, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run báa sọ fún, Bárúkì sì kọ láti ẹnu Jeremáyà, gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ fún-un sórí ìwé kíká náà.

5. Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún Bárúkì pé, “A ṣé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa.

6. Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ ààwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíkà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Júdà, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn.

7. Ó lè jẹ́ pé, ẹbọ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.”

8. Bárúkì ọmọ Neráyà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremáyà sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa.

9. Ní oṣù kẹ́sàn-án ọdún karùn-ún Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà ni wọ́n kéde ààwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti Júdà.

10. Láti inú yàrá Gémáríà ọmọ Sáfánì akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Bárúkì sì ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.

11. Nígbà tí Míkáyà ọmọ Gémáríà ọmọ Sáfánì gbọ́ gbogbo àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé náà;

12. Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé Ọba sínú yàrá akọ̀wé; níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí: Élísámà akọ̀wé, Déláyà ọmọ Sámáyà, Elinátanì ọmọ Ákíbórì, Gémáríà ọmọ Sáfánì àti Sedekáyà ọmọ Hananáyà àti gbogbo àwọn ìjòyè.

13. Lẹ́yìn tí Míkáyà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí o ti gbọ́ fún wọn, nígbà tí Bárúkì kà láti inú ìwé kíkà náà ní etí àwọn ènìyàn.

14. Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jéhúdù ọmọ Métamáyà ọmọ Sélémáyà ọmọ Kúsì sí Bárúkì wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Bárúkì ọmọ Nétayà wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀.

15. Wọ́n sì wí fún pé, “Jòkòó, jọ̀wọ́ kà á sí etí wa!”Nígbà náà ni Bárúkì sì kàá ní etí wọn.

Ka pipe ipin Jeremáyà 36