Láti inú yàrá Gémáríà ọmọ Sáfánì akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Bárúkì sì ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.