Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 35:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Ígídálíà, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Mááséíà, ọmọ Sálúmù, olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà,

5. Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rékábù. Mo sì wí fún wọn pé, “Mu ọtí wáìnì.”

6. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jónádábù ọmọ Rékábù, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé

7. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbití ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’

8. Báyìí ni àwa gba ohùn Jónádábù ọmọ Rékábù bàbá wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó palásẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa.

9. Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn.

10. Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́ràn, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jónádábù baba wa paláṣẹ fún wa.

11. Ó sì se, nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Síríà.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jérúsálẹ́mù.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 35