Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 35:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehóaikimu ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà wí pé:

2. “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rékábù, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”

3. Nígbà náà ni mo mu Jmanáyà ọmọ Jeremáyà, ọmọ Hábásínáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rékábù.

4. Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Ígídálíà, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Mááséíà, ọmọ Sálúmù, olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà,

Ka pipe ipin Jeremáyà 35