Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 33:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “ ‘Síbẹ̀, èmi ó mú okun àti ìwòsàn wá; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn ìyè lọ́pọ̀lọpọ̀ àti ìṣọ́.

7. Èmi ó mú Júdà àti Ísírẹ́lì kúrò nínú ìgbékùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀.

8. Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sími. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedédé wọn sí mi jìn wọ́n.

9. Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèṣè fún wọn.’

10. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ilẹ̀ yìí pé ó dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran. Síbẹ̀ ní ìlú Júdà ní pópónà ti Jérúsálẹ́mù tí ó di àkọsílẹ̀ láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; yálà ní ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, wọn ó gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí.

11. Ariwo di ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé:“Yin Olúwa àwọn ọmọ ogun,nítorí Olúwa dára,ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.”Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀ ni Olúwa wí:

12. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi.

13. Ní ìlú orílẹ̀ èdè òkè wọn, ní ìhà gúṣù ilẹ̀ olókè ní ilẹ̀ ti Bẹ́ńjámínì ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà ni agbo yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí.

14. “ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ṣẹ.

15. “ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì àti ní àkókò náà,Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dáfídì.Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.

16. Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, Júdà yóò di ẹni ìgbàlà.Jérúsálẹ́mù yóò sì máa gbé láìséwuOrúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’

17. Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dáfídì kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Jeremáyà 33