Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 33:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jeremáyà wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì:

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹni tí ó dá ayé, Olúwa tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, Olúwa ni orúkọ rẹ̀:

3. ‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’

4. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn Ọba Júdà tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà

5. Nínú ìjà pẹ̀lú Kálídéà: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn.

6. “ ‘Síbẹ̀, èmi ó mú okun àti ìwòsàn wá; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn ìyè lọ́pọ̀lọpọ̀ àti ìṣọ́.

7. Èmi ó mú Júdà àti Ísírẹ́lì kúrò nínú ìgbékùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀.

8. Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sími. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedédé wọn sí mi jìn wọ́n.

9. Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèṣè fún wọn.’

10. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ilẹ̀ yìí pé ó dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran. Síbẹ̀ ní ìlú Júdà ní pópónà ti Jérúsálẹ́mù tí ó di àkọsílẹ̀ láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; yálà ní ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, wọn ó gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí.

11. Ariwo di ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé:“Yin Olúwa àwọn ọmọ ogun,nítorí Olúwa dára,ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.”Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀ ni Olúwa wí:

Ka pipe ipin Jeremáyà 33