Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 31:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Èmi yóò tún gbé e yín sókè,àní a ó tún gbé e yín ró iwọ wúndíá ilẹ̀ Ísírẹ́lì.Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.

5. Ẹ ó tún dá okoní orí òkè Saáríà;àwọn àgbẹ̀ yóò sì máagbádùn èso oko wọn.

6. Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jádelórí òkè Éfráímù wí pé,‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Síónì,ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”

7. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:“Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù;ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo.Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì.’

8. Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.

9. Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún,wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà.Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi;ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú,nítorí èmi ni baba Ísírẹ́lì,Éfúráímù sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.

10. “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀ èdèẹ kéde rẹ̀ ní erékùsù jínjìn;‘Ẹni tí ó bá tú Ísírẹ́lì ká yóò kójọ,yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn.’

11. Nítorí Olúwa ti tú Jákọ́bù sílẹ̀, o sì ràá padàní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ

12. Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Síónì;wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróróọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,ìkorò kò ní bá wọn mọ́.

13. Àwọn wúndíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.

14. Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀;àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,”ni Olúwa wí.

15. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“A gbọ́ ohùn kan ní Rámàtí ń sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.Rákélì ń sọkún fún àwọn ọmọ rẹ̀;kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 31