Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 31:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí Olúwa ti tú Jákọ́bù sílẹ̀, o sì ràá padàní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ

12. Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Síónì;wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróróọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,ìkorò kò ní bá wọn mọ́.

13. Àwọn wúndíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin.Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú.Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.

14. Èmi ó tẹ́ àwọn àlùfáà lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pọ̀;àwọn ènìyàn mi yóò sì kún fún oore mi,”ni Olúwa wí.

15. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“A gbọ́ ohùn kan ní Rámàtí ń sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò.Rákélì ń sọkún fún àwọn ọmọ rẹ̀;kò gbà kí wọ́n tu òun nínú,nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”

16. Báyìí ni Olúwa wí:“Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkúnàti ojú rẹ nínú omijé;nítorí a ó fi èrè sí isẹ́ rẹ,”ni Olúwa wí.“Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.

17. Nítorí ìrètí wà fún ọjọ́ iwájú rẹ,”ni Olúwa wí.“Àwọn ọmọ rẹ yóò padà wá sí ilẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin Jeremáyà 31