Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 30:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,Ọba wọn yóò dìde láti àárin wọn.Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jìn láti súnmọ́ mi?

22. Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,’ ”ni Olúwa wí.

23. Wò ó, ìbínú Ọlọ́run yóò tú jáde,ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.

24. Ìbínú ńlá Ọlọ́run kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìnàwọn ìkà títí yóò fi múèròǹgbà ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Ní àìpẹ́ ọjọ́,òye rẹ̀ yóò yé e yín.

Ka pipe ipin Jeremáyà 30