Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 29:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jérúsálẹ́mù sí àwọn tí ó yè nínú àwọn aṣàtìpó àti àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn Nebukadinésárì tí wọ́n ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì.

2. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀yìn ìṣèjọba Jéhóíákímù àti ayaba àti ìwẹ̀fà pẹ̀lú àwọn olórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, àwọn gbẹ́nà gbẹ́nà àti àwọn olùyàwòrán tí wọ́n lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù.

3. Ó fi lẹ́tà náà rán Élásà ọmọ Híkáyà ti Ṣédà.

4. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì:

5. “Ó kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.

6. Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fọ́kọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ síi ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá.

7. Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ire ilẹ̀, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ire ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.”

8. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárin yín tàn yín jẹ. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá.

9. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi; Èmi kò rán wọn níṣẹ́,” ni Olúwa wí.

10. Báyìí ni Olúwa wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jérúsálẹ́mù.

11. Nítorí mo mọ ète tí mo ní fún un yín,” ni Olúwa wí, “Ète láti mú yín lọ́rọ̀ láìpa yín lára, ète láti fún un yín ní ìrètí ọjọ́ iwájú.

12. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.

13. Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí.

14. Èmi yóò sì mú yín kúrò ní ìgbékùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀ èdè àti ibi gbogbo tí mo ti lé yín jáde. Èmi yóò sì kó yín padà sí Jérúsálẹ́mù ibi tí mo ti kó jáde lọ sí ilé àtìpó.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 29