Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 28:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananáyà ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremáyà wí pé:

13. “Lọ sọ fún Hananáyà, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní àyè wọn, wà á bá àjàgà onírin.

14. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mà á fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀ èdè láti lè máa sin Nebukadinésárì ti Bábílónì, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Mà á tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”

15. Wòlíì Jeremáyà sọ fún Hananáyà wòlíì pé, “Tẹ́tí, Hananáyà! Olúwa ti rán ọ, síbẹ̀, o rọ orílẹ̀ èdè yìí láti gba irọ́ gbọ́.

16. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí Olúwa.’ ”

17. Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananáyà wòlíì kú.

Ka pipe ipin Jeremáyà 28