Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 26:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà tí Ọba Jéhóíákímù àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Úráyà gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Éjíbítì.

22. Ọba Jéhóíákímù rán Elinátanì ọmọ Álíbórì lọ sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn.

23. Wọ́n sì mú Úráyà láti Éjíbítì lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Jéhóíákímù; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)

24. Áhíkámù ọmọ Sáfánì ń bẹ pẹ̀lú Jeremáyà, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.

Ka pipe ipin Jeremáyà 26