Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 26:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Dúró ní àgbàlà ilé Olúwa, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Júdà tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa: sọ gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.

3. Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọọkan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.

4. Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé síwájú yín.

5. Àti tí ẹ kò bá fetísí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò fetí sílẹ̀.

6. Mà á jẹ́ kí ilé yìí dàbí sílò, n ó sọ ìlú yìí kí ó dàbí ìfibú fún gbogbo àgbáyé.’ ”

7. Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremáyà tí ó sọ ní ilé Olúwa.

8. Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremáyà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí Olúwa pa láṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dì í mú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú!

9. Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí ṣílò, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremáyà nínú ilé Olúwa.

10. Nígbà tí àwọn aláṣẹ Júdà gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin sí ilé Olúwa, wọ́n sì mú àyè wọn, wọ́n jòkòó ní ẹnu ọ̀nà tuntun ilé Olúwa.

11. Àwọn àlùfáà àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”

12. Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “Olúwa rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.

Ka pipe ipin Jeremáyà 26