Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 26:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Ọba Jehóáíkímù ọmọ Jòsáyà tí ń ṣe Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:

2. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Dúró ní àgbàlà ilé Olúwa, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Júdà tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa: sọ gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.

3. Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọọkan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.

4. Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé síwájú yín.

5. Àti tí ẹ kò bá fetísí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò fetí sílẹ̀.

6. Mà á jẹ́ kí ilé yìí dàbí sílò, n ó sọ ìlú yìí kí ó dàbí ìfibú fún gbogbo àgbáyé.’ ”

7. Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremáyà tí ó sọ ní ilé Olúwa.

8. Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremáyà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí Olúwa pa láṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dì í mú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú!

Ka pipe ipin Jeremáyà 26