Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 21:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremáyà wá nígbà tí Ọba Sedekáyà rán Páṣúrì ọmọ Málíkíjà àti àlùfáà Sedekáyà ọmọ Mánásè síi; wọ́n wí pé:

2. “Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”

3. Ṣùgbọ́n Jeremáyà dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekáyà,

4. ‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá Ọba àti àwọn ará Bábílónì tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.

5. Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle.

6. Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-àrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú.

7. Olúwa sọ pé lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò fi Sedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ogun àti ìyàn lé Ọba Nebukadinésárì àti Bábílónì àti gbogbo ọ̀ta wọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òun yóò sì fi idà pa wọ́n, kì yóò sì ṣàánú wọn.’

8. “Síwájú síi, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín.

9. Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Bábílónì tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.

10. Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí níyà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún Ọba Bábílónì, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’

Ka pipe ipin Jeremáyà 21