‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá Ọba àti àwọn ará Bábílónì tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.