Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 20:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Olúwa alágbára, ìwọ tí ó ń dán olódodo pípé wòtí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀yà fínní-fínní,jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.

13. Kọrin sí Olúwa!Fi ìyìn fún Olúwa!Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìnílọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.

14. Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.

15. Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,“A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”

16. Kí ọkùnrin náà dàbí ìlútí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáànúKí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,ariwo ogun ní ọ̀sán.

17. Nítorí kò pa mí nínú,kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi,kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.

18. Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn,láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?

Ka pipe ipin Jeremáyà 20