Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 2:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máajẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin sì wá, ẹ sìba ilẹ̀ náà jẹ́, ẹ sì mú àwọnohun ogún mi di ohun ìríra.

8. Àlùfáà kò bèèrè wí pé níbo ni Olúwa wà? Àwọn tí ń ṣiṣẹ́pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọnolórí wọn sì gbógun sí mi,àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípaòrìṣà báálì, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọnòrìṣà yẹpẹrẹ.

9. “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ́kan síi,”ni Olúwa wí.“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ

10. Rékọjá sí ẹkùn kan kítímì, kí osì wò ó, ránṣẹ́ sí kéda, kí o sìwò ó dáradára, wò ó kí ẹ sìwò ó bí irú nǹkan báyìí báwà níbẹ̀ rí?

11. Orílẹ̀ èdè kan há á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà?(Síbẹ̀, wọn kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run)àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.

Ka pipe ipin Jeremáyà 2