Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 2:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Níbo wá ni àwọn Ọlọ́run (kékeré) tíẹ ṣe fúnra yín há a wà?Jẹ́ kí wọn wá kí wọn sìgbà yín nígbà tí ẹ báwà nínú ìṣòro! Nítorí péẹ̀yin ní àwọn Ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́bí ẹ ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Júdà.

29. “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”ni Olúwa wí.

30. “Nínú aṣán mo fìyà jẹ àwọnènìyàn yín, wọn kò sì gbaìbáwí, idà yín ti pa àwọnwòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bíkìnnìún tí ń bú ramúramù.

31. “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ Olúwa:“Àbí ilẹ̀ ńlá olókùnkùnkí ló dé tí àwọn ènìyàn mi ṣesọ wí pé, ‘A ní àǹfààní látimáa rìn kiri? A kò sì ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́?’

32. Wúndíá ha le gbàgbé ohunọ̀ṣọ́ rẹ̀ bí, tàbí ìyàwó ha le gbàgbé ohunọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? Síbẹ̀, àwọnènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.

Ka pipe ipin Jeremáyà 2