Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 2:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Lọ kéde sí etí ìgbọ́ àwọn Jérúsálẹ́mù:“ ‘Mo rántí ìfarasìn ìgbà èwe rẹ,gẹ́gẹ́ bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi bí i wúndíá àti bí o ṣe tẹ̀lé mi nínú aṣálẹ̀ àti nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.

3. Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́ sí Olúwa, àkọ́kọ́èṣo ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí óbá jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ìpọ́njúyóò dé bá wọn,’ ”bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

4. Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jákọ́bùàti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Ísírẹ́lì.

5. Báyìí ni Olúwa wí:“Irú àwọn àìṣedédé wo ni baba yín rí nínú mi?Tí wọ́n fi jìnnà sími? Wọ́n tẹ̀léàwọn òrìṣà tí kò jámọ́ nǹkan kanàwọn fúnra wọn sì jẹ́ ènìyàn yẹpẹrẹ.

6. Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà tí ó mú wọn,jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì, tí ó mú wala ihà já, tí ó mu wọn la àárin àwọnaṣálẹ̀ àti òkè láàrin ìyàngbẹ ilẹ̀àti òkùnkùn wá ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́nikò ti rìnrìn-àjò, tí ẹníkẹ́ni kò sì gbé?’

7. Mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máajẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin sì wá, ẹ sìba ilẹ̀ náà jẹ́, ẹ sì mú àwọnohun ogún mi di ohun ìríra.

8. Àlùfáà kò bèèrè wí pé níbo ni Olúwa wà? Àwọn tí ń ṣiṣẹ́pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọnolórí wọn sì gbógun sí mi,àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípaòrìṣà báálì, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọnòrìṣà yẹpẹrẹ.

9. “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ́kan síi,”ni Olúwa wí.“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ

10. Rékọjá sí ẹkùn kan kítímì, kí osì wò ó, ránṣẹ́ sí kéda, kí o sìwò ó dáradára, wò ó kí ẹ sìwò ó bí irú nǹkan báyìí báwà níbẹ̀ rí?

11. Orílẹ̀ èdè kan há á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà?(Síbẹ̀, wọn kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run)àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.

12. Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀ méjìkí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”ni Olúwa wí.

13. “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́sẹ̀, méjìWọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmiorísun omi ìyè, wọ́n sì tiwọ àmù, àmù fífọ́ tí kò lègba omi dúró.

14. Ísírẹ́lì há á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ẹrú nípa ìbí? Kí ló há adé tí ó fi di ìkógun?

15. Àwọn kìnnìún ké ramúramúwọ́n sì ń bú mọ́ wọnwọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfòÌlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sìti di ìkọ̀sílẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 2