Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 18:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ṣe kí a fi rere san búburú?Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi,rántí pé mo dúró níwájú rẹ,mo sì sọ̀rọ̀ ní torí wọn, látiyí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

21. Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọnjọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idàjẹ́ kí ìyàwó wọn aláìlọ́mọ àti opójẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọnkí a sì fi idà pa àwọn ọdọ́mọkùnrinwọn lójú ogun.

22. Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọnnígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagunkọ lù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ ìkẹkùn fún ẹṣẹ̀ mi

23. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ gbogboète wọn láti pa mí, má ṣe fojú fòibi wọn tàbí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúròlójú rẹ. Jẹ́ kí a mú wọn kúrò níwájú rẹbá wọn jà nígbà ìbínú rẹ.

Ka pipe ipin Jeremáyà 18