Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 16:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.”

3. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti bàbá wọn.

4. “Wọn yóò kú ikú àrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú ọ̀kọ̀ àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”

5. Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má se lọ ibẹ̀ láti káànú tàbí sọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú ìbùkún, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí.

6. “Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn.

7. Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í sọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún bàbá tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú.

8. “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àsà wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu.

Ka pipe ipin Jeremáyà 16