Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 16:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.”

3. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti bàbá wọn.

4. “Wọn yóò kú ikú àrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí sọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú ọ̀kọ̀ àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 16