Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 13:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Júdà mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’

12. “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí: Gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’

13. Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

14. Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí: Èmi kì yóò dáríjìn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti má a pa wọ́n run.’ ”

15. Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀,ẹ má ṣe gbéraga,nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

16. Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín,kí ó tó mú òkùnkùn wá,àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsélórí òkè tí ó ṣókùnkùn,Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀,òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò si ṣe bi òkùnkùn biribiri.

17. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,Èmi yóò sunkún ní ìkọ̀kọ̀nítorí ìgbéraga yín;Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,tí omi ẹkún, yóò sì máa ṣàn jáde,nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

18. Sọ fún Ọba àti ayaba pé,“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”

19. Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní Négéfì ni à ó tì pa,kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti sí wọn.Gbogbo Júdà ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,gbogbo wọn ni a ó kó lọ pátapáta.

Ka pipe ipin Jeremáyà 13