Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 13:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi, “Lọ ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ́ kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.”

2. Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.

3. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì:

4. Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fi wé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Pérátì kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.

5. Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Pérátì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.

6. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi: Lọ sí Pérátì kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.

7. Nígbà náà ni mo lọ sí Pérátì mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsín yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.

8. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

9. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Júdà àti ìgbéraga ńlá ti Jérúsálẹ́mù.

10. Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun.

11. Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Ísírẹ́lì àti gbogbo ilé Júdà mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’

12. “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí: Gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’

13. Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

Ka pipe ipin Jeremáyà 13